29
Iwo to fe wa la o ma sin 1. I wo to fe wa la o ma sin titi Oluwa Olore wa Iwo to n so wa n’nu idanwo aye Mimo, logo ola re Baba, iwo l’a o ma sin Baba, iwo l’a o ma bo Iwo to fe wa l’a o ma sin titi Mimo l’ogo ola re. 2. Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’aye T’aye fi nrohun je o Awon to mura lati ma s’oto Won tun nyo n’nu ise re. 3. Iwo to nf’agan lomo to npe ranse Ninu ola re to ga Eni t’o ti s’alaileso si dupe Fun ‘se ogo ola re 4. Eni t’ebi npa le ri ayo ninu Agbara nla re to ga Awon to ti nwoju re fun anu Won tun nyo n’nu ise re. 5. F’alafia re fun ijo re l’aye K’ore-ofe re ma ga; k’awon eni tire ko ma yo titi ninu ogo ise re. Amin.

Yoruba Hymnal

Embed Size (px)

DESCRIPTION

hymn

Citation preview

Page 1: Yoruba Hymnal

Iwo to fe wa la o ma sin

1. I wo to fe wa la o ma sin titiOluwa Olore waIwo to n so wa n’nu idanwo ayeMimo, logo ola re

Baba, iwo l’a o ma sinBaba, iwo l’a o ma boIwo to fe wa l’a o ma sin titiMimo l’ogo ola re.2. Iwo to nsure s’ohun t’a gbin s’ayeT’aye fi nrohun je oAwon to mura lati ma s’otoWon tun nyo n’nu ise re.

3. Iwo to nf’agan lomo to npe ranseNinu ola re to gaEni t’o ti s’alaileso si dupeFun ‘se ogo ola re

4. Eni t’ebi npa le ri ayo ninuAgbara nla re to gaAwon to ti nwoju re fun anuWon tun nyo n’nu ise re.

5. F’alafia re fun ijo re l’ayeK’ore-ofe re ma ga;k’awon eni tire ko ma yo titi ninu ogo ise re. Amin.

Page 2: Yoruba Hymnal

Okan mi yin Oluwa logo

1. Okan mi yin Oluwa logoOba iyanu t’o wa mi riUn o l’agogo iyin y’aye kaUn o si f’ife atobiju han

Oluwa, open i fun OFun ore-ofe t’o fi yan miJowo dimimu titi dopinKi nle joba pelu re loke.

2. Bi eranko l’emi ba segbeBikose ti oyigiyigi ;Lairotele l’Emi Mimo deT’o f’ede titun si mi l’enu.

3. Ayo okan mi ko se rohinLoro, losan, loganjo oru;Gbat’Emi Mimo ti de ‘nu miMo nkorin orun lojojumo

4. Jesu ti la mi loju emiMo si f’eti gbohun ijinle;O nse faji ninu okan mi;Kini mba fi fun Olugbala?

5. Em’o sogo ninu OluwaK’emi ma ba di alaimore;B’o ti pe mi iyanu l’o je;Awon angeli d’olufe mi.

6. Mo damure lati sin JesuLaifotape larin aye yi;Nibikibi t’oba nto mi siO daju ko ni jeki ndamu.

7. Bi mba pari ‘re-ije l’ayeOlugbala, ma je ki npofo;Ni wakati na jeki ngbo peBo sinu ayo ayeraye. Amin.

Page 3: Yoruba Hymnal

B’oruko Jesu ti dun to1. B’oruko Jesu ti dun to,ogo ni fun Oruko Reo tan banuje at’ogbeogo ni fun oruko Re

ogo f’oko Re, ogo f’oko Reogo f’oruko Oluwaogo f’oko Re, ogo f’oko Reogo f’oruko Oluwa

2. O wo okan to gb’ogbe sanOgo ni fun oruko ReOnje ni f’okan t’ebi npaOgo ni fun oruko Re

3. O tan aniyan elese,Ogo ni fun oruko ReOfun alare ni simiOgo ni fun oruko Re

4. Nje un o royin na f’elese,ogo ni fun oruko rePe mo ti ri OlugbalaOgo ni fun oruka Re. Ko su wa lati ma ko orin ti igbani

1. Ko su wa lati ma ko orin ti igbaniOgo f’olorun AleluyaA le fi igbagbo korin na s’oke kikanOgo f’olorun, Aleluya!

Omo olorun ni eto lati ma bu s’ayoPe ona yi nye wa si,Okan wa ns’aferi ReNigb’o se a o de afin Oba wa ologo,Ogo f’olorun, Aleluya!

2. Awa mbe n’nu ibu ife t’o ra wa pada,ogo f’olorun Aleluya!Awa y’o fi iye goke lo s’oke orun

Page 4: Yoruba Hymnal

Ogo f’olorun, Aleluya!

3. Awa nlo si afin kan ti a fi wura ko,ogo f’olorun Aleluya!Nibiti a ori Oba ogo n’nu ewa ReOgo f’olorun, Aleluya!

4. Nibe ao korin titun t’anu t’o da wa ndeOgo f’olorun Aleluya!Nibe awon ayanfe yo korin ‚yin ti Krist;Ogo f’olorun, Aleluya!. Amin

 WA BA MI GBE1. Wa ba mi gbe, ale fere le tanOkunkun nsu, Oluwa ba mi gbe;Bi oluranlowo miran ba yeIranwo alaini, wa ba mi gbe

2. Ojo aye mi nsare lo s’opinAyo aye nku, ogo re nwomiAyida at’ibaje ni mo n ri‘wo ti ki yipada, wa ba mi gbe

3. Ma wa l’eru b’Oba awon obaB’oninure, wa pelu ‘wosan Re?Ki Ossi ma kanu fun egbe miWa, ore elese, wa ba mi gbe.

4. Mo nfe O ri, ni wakati gbogboKilo le swgun esu b’ore Re?Tal’o le se amona mi bi Re?N’nu ‘banuje at’ayo ba mi gbe

5. Pelu ‘bukun Re, eru ko ba miIbi ko wuwo, ekun ko koro,oro iku da? ‚segun isa da?Un o segun sibe, b’iwo ba mi gbe.

6. Wa ba mi gbe, ni wakati iku,

Page 5: Yoruba Hymnal

Se ‘mole mi, si toka si orunB’aye ti nkoja, k’ile orun moNi yiye, ni kiku, wa ba mi gbe. Amin. FI IYIN FUN JESU OLURAPADA WA

1. Fi iyin fun Jesu, Olurapada wa,Ki aye k’okiki ife Re nla ;Fi iyin fun ! eyin Angeli ologo,F’ola at’ogo fun oruko re,B’olu’agutan, Jesu y’o to omo ReL’apa Re l’o ngbe won le l’ojojoEyin eniyan mimo ti ngb’oke SionFi iyin fun pelu orin ayo

2. Fi iyin fun, Jesu Olurapada wa,Fun wa, O t’eje Re sile, O kuOn ni apata, ati reti ‘gbala wa,Yin Jesu ti a kan m’agbelebu;Olugbala t’O f’ara da irora nlaTi a fi ade egun de loriEniti a pa nitori awa edaOba ogo njoba titi laelae.

3. Fi iyin fun, Jesu Olurapada waKi ariwo iyin gba orun kanJesu Oluwa njoba lae ati laelae,Se l’oba gbogb’eyin alagbaraA segun iku; fi ayo royin na kaIsegun re ha da, isa oku?Jesu ye ko tun si wahala fun wa mo‘tori O l’agbara lati gbala. Amin. E JE J’A F’INU DIDUN

1. Eje k’a f’inu didunYin Oluwa OloreAnu Re O wa titiLododo dajudaju

2. On nipa agbara ReF’imole s’aye titun

Page 6: Yoruba Hymnal

Anu Re, O wa titiLododo dajudaju

3. O mbo gbogb’eda ‘layeO npese fun aini wonAnu re, O wa titiLododo dajudaju

4. O bukun ayanfe ReLi aginju iparunAnu re O wa titiLododo dajudaju

5. E je k’a f’inu didunYin Oluwa OloreAnu Re, O wa titiLododo dajudaju. Amin. EMI ‘BA N’EGBERUN AHON

1 E mi ‘ba n’egberun ahon,Fun ‘yin OlugbalaOgo Olorun Oba miIsegun Ore Re.

2. Jesu t’o seru wa d’ayoT’o mu banuje tanOrin ni l’eti eleseIye at’ilera.

3. O segun agbara eseO da onde sileEje Re le w’eleri moEje Re le w’eleri moEje Re seun fun mi

4. O soro, oku gb’ohun ReO gba emi titun ;O niro binuje je y’ayoOtosi si gbagbo

5. Odi, e korin iyin re

Page 7: Yoruba Hymnal

Aditi , gbohun ReAfoju, Olugbala de, Ayaro, fo f’ayo

6. Baba mi at’olorun mi,Fun mi ni ‘ranwo ReKi nle ro ka gbogbo ayeOla oruko Re. Amin. E WOLE F’OBA, OLOGO JULO

1. E wole f’oba, Ologo juloE korin ipa ati ife ReAlabo wa ni at’eni igbaniO ngbe ‘nu ogo, Eleru ni iyin

2. E so t’ipa Re, e so t’ore Re‘mole l’aso Re, gobi Re orunAra ti nsan ni keke ‘binu Re jeIpa ona Re ni a ko si le mo

3. Aye yi pelu ekun ‘yanu ReOlorun agbara Re l’oda wonO fi id ire mule, ko si le yiO si f’okan se aso igunwa Re.

4. Enu ha le so ti itoju Re ?Ninu afefe ninu imoleItoju Re wa nin’odo ti o nsanO si wa ninu iri ati ojo

5. Awa erupe aw’alailera‘wo l’a gbekele, o ki o da niAnu Re rorun o si le de opinEleda, Alabo, Olugbala wa

6. ‘wo Alagbara Onife juloB’awon angeli ti nyin O lokeBe l’awa eda Re, niwon t’a le seA o ma juba Re, a o ma yin O. Amin.

Page 8: Yoruba Hymnal

 GBOGBO AYE , GBE JESU GA

1. Gbogbo aye, gbe Jesu ga,Angel’, e wole funE mu ade Oba Re wa,Se l’Oba awon oba

2. E se l’Oba eyin Martyr,Ti npe ni pepe ReGbe gbongbo igi Jese gaSe l’Oba awon oba

3. Eyin iru omo Isreal’Ti a ti rapadaE ki Eni t’ogba yin laSe l’Oba awon oba

4. Gbogbo eniyan eleseRanti ‘banuje yinE te ‘kogun yin s’ese ReSe l’Oba awon oba

5. Ki gbogbo orile edeNi gbogbo agbayeKi won ki, « Kabiyesile »Se l’Oba awon oba

6. A ba le pel’awon t’orunLati ma juba ReK’a bale jo jumo korinSe l’Oba awon oba. Amin. Okan mi yin Oba orun

1. Okan mi yin Oba orunMu ore wa sodo re‘Wo ta wosan, t’a darijiTal’aba ha yin bi Re ?Yin Oluwa, yin OluwaYin Oba ainipekun

Page 9: Yoruba Hymnal

2. Yin fun anu t’o ti fi hanF’awon Baba ‘nu ponjuYin L Okan na ni titiO lora lati binuYin Oluwa, yin OluwaOlogo n’u otito

3. Bi baba ni O ntoju waO si mo ailera waJeje l’o ngbe wa lapa ReO gba wa lowo otaYin Oluwa, yin OluwaAnu Re, yi aye ka

4. Angel, e jumo ba wa boEyin nri lojukojuOrun, Osupa, e woleAti gbogbo agbayeE ba wa yin, e ba wa yinOlorun Olotito. Amin. SI O OLUTUNU ORUN

1. Si o Olutunu OrunFun ore at’agbara ReA nko, Aleluya

2. Si O, ife eni t’OwaNinu Majemu OlorunA nko, Aleluya

3. Si O agbara Eni tiO nwe ni mo, t’o nwo ni sanA nko, Aleluya

4. Si O, Oluko at’oreAmona wa toto d’opinA nko, Aleluya.

5. Si O, Eniti Kristi ranAde on gbogbo ebun re

Page 10: Yoruba Hymnal

A nko, Aleluya. Amin. MIMO, MIMO, MIMO, OLODUMARE1. Mimo, mimo,mimo, OlodumareNi kutukutu n’iwo O gbo orin waMimo, mimo, mimo ! Oniyonu juloOlogo meta, lae Olubukun

2. Mimo, mimo, mimo ! awon t’orun nyinWon nfi ade wura won le ‘le yi ‘te kaKerubim, serafim nwole niwaju ReWo t’o ti wa, t’O si wa titi lae.

3. Mimo, mimo,mimo ! b’okunkun pa o moBi oju elese ko le ri ogo reIwo nikan l’O mo, ko tun s’elomiranPipe ‘nu agbara ati n’ife.

4. Mimo, mimo, mimo ! OlodumareGbogbo ise Re n’ile l’oke l’o nyin OMimo, mimo, mimo ! Oniyonu juloOlogo meta lae Olubunkun ! Amin. A F’OPE F’OLORUN

1. A f’ope f’olorunL’okan ati l’ohun waEni s’ohun ‘yanuN’nu eni t’araye nyo‘gbat’a wa l’om’owoOn na l’o ntoju waO si nf’ebun ifeSe ‘toju wa sibe.

2. Oba Onib’oreMa fi w asile laelaeAyo ti ko l’opinOn ‘bukun y’o je ti waPa wa mo n’nu oreTo wa, gb’a ba damuYo wa ninu ibiL’aye ati l’orun

Page 11: Yoruba Hymnal

3. K’a f’iyin on opeF’Olorun, Baba, OmoAti Emi mimoTi O ga julo lorunOlorun kan laelaeT’aye at’orun mboBe l’o wa d’isiyiBeni y’o wa laelae. Igba Mi d’owo Re

1. I gba mi d’owo ReMo fe k’O wa nibeMo f’ara, ore, emi miSi abe iso Re

2. Igba mi d’owo ReEyi t’o wu k’o jeDidun ni tabi kikoroB’O ba ti ri p’o to.

3. Igba mi d’owo ReEmi y’o se beru ?Sokun li ainidi

4. Igba mi d’owo ReJesu t’a kan mo ‘giOwo na t’ese mi daluWa di alabo mi

5. Igba mi d’owo Re‘wo ni ngo gbekeleLeyin iku, low’otun ReL’em’o wa titi lae. Amin.

 Elese e yipada

1. Elese e yipada,Ese ti e o fi ku ?Eleda yin ni mbere

Page 12: Yoruba Hymnal

To fe ki e ba On gbeOran nla ni O mbi yinIse owo Re ni yinA ! eyin alailopeEse t’eo ko ‘fe Re ?

2. Elese e yi padaEse ti e o fi ku ?Olugbala ni mbereEni t’O gb’emi yin laIku Re y’o j’asan bi ?E o tun kan mo ‘gi bi ?Eni ‘rapada eseTe o gan or’ofe Re ?

3. Elese e yi padaEse ti e o fi ku ?Emi mimo ni mbereTi nf’ojo gbogbo ro yinE ki o ha gb’ore Re ?E o ko iye sibe ?Ati nwa yin pe eseT’e mbi Olorun ninu ?

4. Iyemeji ha nse yinPe ife ni OlorunE ki o ha gboro Re ?K’e gba ileri Re gbo ?W’Oluwa lodo yinJesu sun, w’omije ReEje Re pelu nke peEse ti e o fi ku ?. Amin. Aye si mbe ! ile Od’agutan

1. Aye si mbe ! ile Od’agutanEwa ogo re npe o pe « ma bo »Wole, wole, wole nisisiyi

2. Ojo lo tan, orun si fere woOkunkun de tan, ‘mole nkoja loWole, wole, wole nisisiyi

Page 13: Yoruba Hymnal

3. Ile iyawo na kun fun aseWole, wole to oko ‘yawo loWole, wole, wole nisisiyi

4. O nkun ! o nkun ! ile ayo na nkunYara ! mase pe ko kun ju fun O !Wole,wole,wole nisisiyi.

5. Aye si mbe ilekun si sileIlekun ife, iwo ko pe juWole, wole, wole nisisiyi

6. Wole, wole ! tire ni ase naWa gb’ebun ‘fe ayeraye lofe !Wole, wole wole nisisiyi.

7. Kiki ayo l’o wa nibe, wole !Awon angeli npe o fun adeWole, wole, wole nisisiyi.

8. L’ohun rara n’ipe ife na ndun !Wa ma jafara, wole, ase na !Wole, wole, wole nisisiyi

9. K’ile to su, ilekun na le ti‘gba na o k’abamo ! « o se ! o se ! »O se, o se, ko s’aye mo o se !. Amin. Wa s’odo Jesu, mase duro

1. Wa s’odo Jesu, mase duroL’oro Re l’o ti fona han waO duro li arin wa loniO nwi pele pe wa!Ipade wa yio je ayoGb’okan wa ba bo lowo eseT’a o si wa pelu Re JesuN’ile ayeraye

2. Jek’omode wa ! E gb’ohun ReJek’okan gbogbo kun fun ayo

Page 14: Yoruba Hymnal

K’a si yan Jesu l’ayanfe waE ma duro, e wa.

3. Ranti p’O wa pelu wa loniF’eti s’ofin Re, k’o si pamoGbo b’ohun Re ti nwi pele peEyin omo Mi wa. Bi Kristi’ ti da okan mi nde

1. Bi Kristi’ ti da okan mi ndeAye mi ti dabi orunLarin ‘banuje at’aroAyo ni lati mo Jesu

Aleluya ! ayo l’o jePe mo ti ri ‘dariji gbaIbikibi ti mo ba waKo s’ewu, Jesu wa nibe

2. Mo ti r ope orun jinaSugbon nigbati Jesu deL’orun ti de ‘nu okan miNibe ni y’o si wa titi

3. Nibo l’a ko le gbe l’ayeL’o r’oke tabi peteleL’ahere tabi agbalaKo s’ewu, Jesu wa nibe. Amin. Bi mo ti ri, lai s’awawi

1. Bi mo ti ri, lai s’awawiSugbon nitori eje ReB’o si ti pe mi pe ki nwaOlugbala, mo de.

2. Bi mo ti ri, laiduro peMo fe k ‘okan mi mo totoS’odo Re to le we mi moOlugbala, mo de

Page 15: Yoruba Hymnal

3. Bi mo ti ri, b’o tile jeIja l’ode, ija ninuEru l’ode, eru ninuOlugbala, mo de

4. Bi mo ti ri, osi areMo si nwa imularadaIwo le s’awotan miOlugbala, mo de.

5. Bi mo ti ri ‘wo o gba mi‘wo o gba mi, t’owo t’ese‘tori mo gba ‘leri Re gboOlugbala, mo de.

6. Bi mo ti ri ife TireL’o sete mi patapataMo di Tire, Tire nikanOlugbala, mo de.

7. Bi mo ti ri, n’nu ‘fe nla niT’o fi titobi Re han miNihin yi ati ni okeOlugbala, mo de. Amin. Olugbala, gb’ohun mi

1. Olugbala, gb’ohun miGb’ohun mi, gb’ohun miMo wa s’odo Re, gba miNibi agbelebuEmi se sugbon O kuIwo ku, iwo kuFi anu Re pa mi moNibi agbelebu

Oluwa, jo gba miNki y’o bi O ninu moAlabukun, gba miNibi agbelebu

2. Ese mi po lapoju

Page 16: Yoruba Hymnal

Un o bebe, un o bebeIwo li Ona iyeNibi agbelebuOre ofe Re t’a gbaL’ofe ni l’ofe niF’oju anu Re wo miN’ibi agbelebu

3. F’eje mimo Re we miFi we mi fi we miRi mi sinu ibu ReN’ibi agbelebu‘gbagbo l’o le fun wa ni‘dariji ‘darijiMo f’igbagbo ro mo oN’ibi agbelebu. Amin. Oluwa, emi sa ti gb’ohun Re

1. Oluwa emi sa ti gb’ohun ReO nso ife Re simiSugbon mo fe nde l’apa igbagboKi nle tubo sun mo o

Fa mi mora, mora, OluwaSib’agbelebu t’O kuFa mi mora, mora, mora OluwaSi b’eje Re t’o n’iye

2. Ya mi si mimo fun ise TireNipa ore-ofe ReJe ki nfi okan igbagbo w’okeK’ife mi si je Tire

3. A ! ayo mimo ti wakati kanTi mo lo nib’ite Re‘gba mo ngb’adura si O OlorunTi a soro bi ore.

4. Ijinle ife mbe ti nko le moTiti un o koja odoAyo giga ti emi ko le so

Page 17: Yoruba Hymnal

Tit un o fi de ‘simi. Amin. Isun kan wa to kun f’eje

1. Isun kan wa to kun f’ejeT’o ti ‘ha Jesu yoElese mokun ninu reO bo ninu ebi

2. ‘Gba mo f’igbagbo r’isun naTi nsan fun eje ReIrapada d’orin fun miTi un o ma ko titi

3. Orin t’odun ju eyi loLi emi o ma ko‘Gbati ore-ofe Re baMu mi de odo Re.

4. Mo gbagbo p’o pese fun miBi mo tile s’aiyeEbun ofe t’a f’eje raAti duru wura

5. Duro t’a t’ow’ Olorun seTi ko ni baje laeTi ao ma fi yin Baba waOruko Re nikan. Amin. Okan mi nyo ninu Oluwa

1. Okan mi nyo ninu Oluwa‘Tori O je iye fun miOhun Re dun pupo lati gboAdun ni lati r’oju Re

Emi nyo ninu ReEmi nyo ninu ReGba gbogbo lo fayo kun okan mi‘Tori emi nyo n’nu Re.

2. O ti pe t’O ti nwa mi kiri

Page 18: Yoruba Hymnal

‘gbati mo rin jina s’agboO gbe mi w asile l’apa ReNibiti papa tutu wa

3. Ire at’anu Re yi mi kaOr’ofe Re nsan bi odoEmi Re nto, o si nse ‘tunuO mba mi lo si ‘bikibi

4. Emi y’o dabi Re ni ‘jo kanUn o s’eru wuwo mi kaleTiti di ‘gbana un o s’olotoNi sise oso f’ade Re. Amin. Ore ofe ohun

1. Ore ofe ohunAdun ni l’eti waGbohun gbohun re y’o gba orun kanAye y’o gbo pelu

Ore ofe saN’igbekele miJesu ku fun arayeO ku fun mi pelu

2. Ore ofe l’o koOruko mi l’orunL’o fi mi fun Od’agutanT’O gba iya mi je.

3. Ore ofe to miS’ona alafiaO ntoju mi l’ojojumoNi irin ajo mi

4. Ore ofe ko miBi a ti ‘gbaduraO pa mi mo titi d’oniKo si je ki nsako

5. Je k’ore ofe yi

Page 19: Yoruba Hymnal

F’agbara f’okan miKi nle fi gbogbo ipa miAt’ojo mi fun O. Amin. IRAPADA ITAN IYANU

1. Irapada ! itan iyanuIhin ayo fun gbogbo waJesu ti ra ‘dariji fun waO san ‘gbese na lor’igi

A ! elese gba ihin na gboJo gba ihin oto na gboGbeke re le Olugbala reT’O mu igbala fun o wa

2. O mu wa t’inu ‘ku bo si ‘yeO si so wa d’om’OlorunOrisun kan si fun eleseWe nin’eje na ko si mo

3. Ese ki y’o le joba wa moB’o ti wu ko dan waw o toNitori Kristi fi ‘rapada Pa ‘gbara ese run fun wa

4. Gba anu t’Olorun fi lo oSa wa s’odo Jesu loni‘Tori y’o gb’enit’o ba t’o waKi yi o si da pada lae. Amin. Aleluya, Ija d’opin, ogun si tan

1. Ija d’opin ogun si tanOlugbala jagun moluOrin ayo lao ma ko – Aleluya

2. Gbogbo ipa n’iku ti loSugbon Kristi f’ogun re kaAye ! e ho iho ayo – Aleluya

3. Ojo meta na ti koja

Page 20: Yoruba Hymnal

O jinde kuro nin’okuE f’ogo fun Oluwa wa – Aleluya

4. O d’ewon orun apadiO silekun orun sileEkorin iyin ‘segun Re – Aleluya

5. Jesu, nipa iya t’O jeGba wa lowo oro ikuK’a le ye ka si ma yin O – Aleluya. Amin. B’elese s’owo po

1. B’elese s’owo poTi won nde s’OluwaDimo si Kristi ReLati gan Oba naB’aye sataPelu EsuEke ni wonWon nse lasan

2. Olugbala jobaLori oke SionAse ti OluwaGbe Omo Tire roLati bojiO ni k’O ndeK’O si gokeK’O gba ni la

3. F’eru sin OluwaSi bowo f’ase ReF’ayo wa sodo ReF’iwariri duroE kunle fun UnK’e teribaSo t’ipa ReKi Omo na !. Amin. MO MO P’OLUDANDE MI MBE

Page 21: Yoruba Hymnal

1. Mo mo p’Oludande mi mbeItunu nla l’eyi fun mi !O mbe, Eni t’o ku lekanO mbe, ori iye mi lae.

2. O mbe lati ma bukun miO si mbebe fun mi lokeO mbe lati ji mi n’bojiLati gba mi la titi lae

3. O mbe, Ore korikosunTi y’o pa mi mo de opinO mbe, emi o ma korinWoli, Alufa, Oba mi

4. O mbe lati pese ayeY’O si mu mi de be l’ayoO mbe, ogo f’oruko ReJesu okan na titi lae

5. O mbe, ogo f’oruko ReOlugbala kanna titiA ! ayo l’oro yi fun mi« Mo mo p’oludande mi mbe ». Amin MI SI MI, OLORUN

1. Mi si mi, OlorunF’emi titun fun miKi nle fe ohun ti O feKi ns’eyi t’O fe se

2. Mi si mi, OlorunS’okan mi di mimoK’ife mi on Tire j’okanL’ero ati n’ise

3. Mi si mi, OlorunTiti un o di TireTi ara erupe mi yiYo tan ‘mole orun

Page 22: Yoruba Hymnal

4. Mi si mi, OlorunEmi ki yo ku laeUn o ba Ogbe n’iwa pipeTiti ayeraye. Amin. ITAN IYANU T’IFE !

1. Itan iyanu t’ife !So fun mi l’ekan siItan iyanu t’ifeE gbe orin na ga !Awon angeli nroyin reAwon oluso si gbagboElese, iwo ki yo gboItan iyanu t’ife

Iyanu ! Iyanu ! Iyanu !Itan iyanu t’ife

2. Itan iyanu t’ifeB’iwo tile sakoItan iyanu t’ifeSibe o npe loniLat’ori oke kalfariLati orisun didun niLati isedale ayeItan iyanu t’ife

3. Itan iyanu t’ifeJesu ni isimiItan iyanu t’ifeFun awon olotoTo sun ni ile nla orunPel’awon to saju wa loWon nko orin ayo orunItan iyanu t’ife. Amin. JESU Y’OGBA ELESE

1. Jesu y’o gba eleseKede re fun gbogb’edaAwon ti won sako lo

Page 23: Yoruba Hymnal

Awon ti won ti subu

Ko l’orin, ko si tun koKristi ngba’awon eleseFi oto na ye won peKristi ngb’awon elese

2. Wa, y’o fun o ni ‘simiGbagbo, oro Re dajuY’o gba eni buru juKristi ngb’awon elese

3. Okan mi da mi lareMo mo niwaju ofinEni t’O ti we mi moTi san gbogbo gbese mi

4. Kristi ngb’awon eleseAn’emi to kun f’eseO ti so mi di mimoMo ba wo ‘joba orun. Amin E YO N’NU OLUWA, E YO

1. E yo n’nu Oluwa, e yo,eyin t’okan re se dedeeyin t’o ti yan Oluwa,le ‘banuje at’aro lo

Eyo! E yo!E yo n’nu Oluwa, e yo!E yo! E yoE yo n’nu Oluwa, e yo!

2. E yo ‘tori On l’OluwaL’aye ati l’orun peluOro Re bor’ohun gbogboO l’agbara lati gbala

3. ‘Gbat’ e ba nja ija rere,Ti Ota f’ere bori yinOgun Olorun t’e ko ri

Page 24: Yoruba Hymnal

Po ju awon ota yin lo

4. B’okunkun tile yi o kaPelu isudede gbogboMase je k’okan re damuSa gbeke l’Oluwa d’opin

5. E yo n’nu Oluwa, e yoE korin iyin Re kikanFi duru ati ohun koAleluya l’ohun goro. Amin.

A SEGUN ATI AJOGUN NI A JE

1. A segun ati ajogun ni a je,Nipa eje Kristi a ni isegunB’Oluwa je tiwa, a ki yo subuKo s’ohun to le bori agbara reAsegun ni wa, nipa eje JesuBaba fun wa ni ‘segun, nipa eje JesuEni t’a pa f’eleseSibe, O wa, O njobaAwa ju asegun loAwa ju asegun lo

2. A nlo l’oruko Olorun IsrealLati segun ese at’aisododoKise fun wa, sugbon Tire ni iyinFun ‘gbala at’isegun ta f’eje ra

3. Eni t’O ba si segun li ao fi funLati je manna to t’orun wa nihinL’orun yo sig be imo ‘pe asegunYo wo ‘so funfun, yo si dade wura. Amin